Native Bible

2 Kings 19:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ìkáàánú rẹ sí mi àti ìrora rẹ dé etí mi, Èmi yóò gbé ìwọ̀ mi sí imú rẹ àti ìjánu mi sí ẹnu rẹ, èmi yóò mú ọ padà nípa wíwá rẹ.’

2 Kings 19:28 in English

2 Kings 19:28 · Berean Standard Bible

Because your rage and arrogance against Me have reached My ears, I will put My hook in your nose and My bit in your mouth; I will send you back the way you came.’

Context

26Àwọn ènìyàn wọn ń gbẹ nípa, wọ́n ti dà á láàmú wọ́n sì ti ṣọ́ di ìtìjú. Wọ́n dàbí koríko igbó lórí pápá, gẹ́gẹ́ bí ọkà tí ó rẹ̀ dànù kí ó tó dàgbàsókè, gẹ́gẹ́ bí fífún ọkà tí ó hù jáde. 27“ ‘Ṣùgbọ́n èmi mọ ibi tí ìwọ dúró àti ìgbà tí ìwọ bá dé tàbí lọ àti bí ìwọ ṣe ìkáàánú rẹ: sí mi. 28Ṣùgbọ́n ìkáàánú rẹ sí mi àti ìrora rẹ dé etí mi, Èmi yóò gbé ìwọ̀ mi sí imú rẹ àti ìjánu mi sí ẹnu rẹ, èmi yóò mú ọ padà nípa wíwá rẹ.’ 29“Èyí yóò jẹ́ àmì fún ọ, ìwọ Hesekiah: “Ọdún yìí ìwọ yóò jẹ ohun tí ó bá hù fún rara rẹ̀, àti ní ọdún kejì ohun tí ó bá hù jáde láti inú ìyẹn. Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, gbìn kí o sì kórè, gbin ọgbà àjàrà kí o sì jẹ èso rẹ̀. 30Lẹ́ẹ̀kan sí i ìyókù ti ilé Juda yóò sì tún hu gbòǹgbò lábẹ́, yóò sì so èso lókè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.