2 Ọba 19:30
2 Kings 19:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́ẹ̀kan sí i ìyókù ti ilé Juda yóò sì tún hu gbòǹgbò lábẹ́, yóò sì so èso lókè.
2 Kings 19:30 in English
2 Kings 19:30 · Berean Standard Bible
And the surviving remnant of the house of Judah will again take root below and bear fruit above.
Context
28Ṣùgbọ́n ìkáàánú rẹ sí mi
àti ìrora rẹ dé etí mi,
Èmi yóò gbé ìwọ̀ mi sí imú rẹ
àti ìjánu mi sí ẹnu rẹ,
èmi yóò mú ọ padà
nípa wíwá rẹ.’ 29“Èyí yóò jẹ́ àmì fún ọ, ìwọ Hesekiah:
“Ọdún yìí ìwọ yóò jẹ ohun tí ó bá hù fún rara rẹ̀,
àti ní ọdún kejì ohun tí ó bá hù jáde láti inú ìyẹn.
Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, gbìn kí o sì kórè,
gbin ọgbà àjàrà kí o sì jẹ èso rẹ̀. 30Lẹ́ẹ̀kan sí i ìyókù ti ilé Juda
yóò sì tún hu gbòǹgbò lábẹ́, yóò sì so èso lókè. 31Láti inú Jerusalẹmu ní àwọn ìyókù yóò ti wá
àti láti orí òkè Sioni ni ọ̀pọ̀ àwọn tí ó sá àsálà.
Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò ṣe èyí. 32“Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa ti ọba Asiria:
“Kò ní wọ ìlú yìí
tàbí ta ọfà síbí.
Kò ní wá níwájú rẹ pẹ̀lú
àpáta tàbí kó ìdọ̀tí àgbò sí ọ̀kánkán rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.