2 Ọba 19:32
2 Kings 19:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa ti ọba Asiria: “Kò ní wọ ìlú yìí tàbí ta ọfà síbí. Kò ní wá níwájú rẹ pẹ̀lú àpáta tàbí kó ìdọ̀tí àgbò sí ọ̀kánkán rẹ.
2 Kings 19:32 in English
2 Kings 19:32 · Berean Standard Bible
So this is what the LORD says about the king of Assyria: ‘He will not enter this city or shoot an arrow into it. He will not come before it with a shield or build up a siege ramp against it.
Context
30Lẹ́ẹ̀kan sí i ìyókù ti ilé Juda
yóò sì tún hu gbòǹgbò lábẹ́, yóò sì so èso lókè. 31Láti inú Jerusalẹmu ní àwọn ìyókù yóò ti wá
àti láti orí òkè Sioni ni ọ̀pọ̀ àwọn tí ó sá àsálà.
Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò ṣe èyí. 32“Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa ti ọba Asiria:
“Kò ní wọ ìlú yìí
tàbí ta ọfà síbí.
Kò ní wá níwájú rẹ pẹ̀lú
àpáta tàbí kó ìdọ̀tí àgbò sí ọ̀kánkán rẹ. 33Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá ni yóò padà;
kì yóò wọ ìlú ńlá yìí,
ni Olúwa wí. 34Èmi yóò dá ààbò bo ìlú ńlá yìí,
èmi yóò sì pa á mọ́ fún èmi tìkára mi àti fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.