Native Bible

2 Kings 19:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá ni yóò padà; kì yóò wọ ìlú ńlá yìí, ni Olúwa wí.

2 Kings 19:33 in English

2 Kings 19:33 · Berean Standard Bible

He will go back the way he came, and he will not enter this city,’ declares the LORD.

Context

31Láti inú Jerusalẹmu ní àwọn ìyókù yóò ti wá àti láti orí òkè Sioni ni ọ̀pọ̀ àwọn tí ó sá àsálà. Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò ṣe èyí. 32“Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa ti ọba Asiria: “Kò ní wọ ìlú yìí tàbí ta ọfà síbí. Kò ní wá níwájú rẹ pẹ̀lú àpáta tàbí kó ìdọ̀tí àgbò sí ọ̀kánkán rẹ. 33Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá ni yóò padà; kì yóò wọ ìlú ńlá yìí, ni Olúwa wí. 34Èmi yóò dá ààbò bo ìlú ńlá yìí, èmi yóò sì pa á mọ́ fún èmi tìkára mi àti fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.” 35Ní alẹ́ ọjọ́ náà, angẹli Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (185,000) ènìyàn ní ibùdó àwọn ará Asiria. Nígbà tí wọ́n sì dìde dúró ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì níbẹ̀ ni gbogbo òkú wà!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.