2 Ọba 19:27
2 Kings 19:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Ṣùgbọ́n èmi mọ ibi tí ìwọ dúró àti ìgbà tí ìwọ bá dé tàbí lọ àti bí ìwọ ṣe ìkáàánú rẹ: sí mi.
2 Kings 19:27 in English
2 Kings 19:27 · Berean Standard Bible
But I know your sitting down, your going out and coming in, and your raging against Me.
Context
25“ ‘Ṣé ìwọ kò tí ì gbọ́?
Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn mo yàn án.
Ní ọjọ́ ogbó ni mo ṣètò rẹ̀;
nísinsin yìí mo ti mú wá sí ìkọjá
pé ìwọ ti yí ìlú olódi padà dí
òkìtì àlàpà òkúta. 26Àwọn ènìyàn wọn ń gbẹ nípa,
wọ́n ti dà á láàmú
wọ́n sì ti ṣọ́ di ìtìjú.
Wọ́n dàbí koríko igbó lórí pápá,
gẹ́gẹ́ bí ọkà tí ó rẹ̀ dànù kí ó tó dàgbàsókè,
gẹ́gẹ́ bí fífún ọkà tí ó hù jáde. 27“ ‘Ṣùgbọ́n èmi mọ ibi tí ìwọ
dúró àti ìgbà tí ìwọ bá dé tàbí
lọ àti bí ìwọ ṣe ìkáàánú rẹ: sí mi. 28Ṣùgbọ́n ìkáàánú rẹ sí mi
àti ìrora rẹ dé etí mi,
Èmi yóò gbé ìwọ̀ mi sí imú rẹ
àti ìjánu mi sí ẹnu rẹ,
èmi yóò mú ọ padà
nípa wíwá rẹ.’ 29“Èyí yóò jẹ́ àmì fún ọ, ìwọ Hesekiah:
“Ọdún yìí ìwọ yóò jẹ ohun tí ó bá hù fún rara rẹ̀,
àti ní ọdún kejì ohun tí ó bá hù jáde láti inú ìyẹn.
Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, gbìn kí o sì kórè,
gbin ọgbà àjàrà kí o sì jẹ èso rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.