Native Bible

2 Kings 16:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ó mú pẹpẹ idẹ tí ó wà níwájú Olúwa kúrò láti iwájú ilé náà, láti àárín méjì pẹpẹ náà, àti ilé Olúwa, ó sì fi í sí apá àríwá pẹpẹ náà.

2 Kings 16:14 in English

2 Kings 16:14 · Berean Standard Bible

He also took the bronze altar that stood before the LORD from the front of the temple (between the new altar and the house of the LORD) and he put it on the north side of the new altar.

Context

12Nígbà tí ọba sì ti Damasku dé, ọba sì rí pẹpẹ náà: ọba sì súnmọ́ pẹpẹ náà, ó sì rú ẹbọ lórí rẹ̀. 13Ó sì sun ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, o si ta ohun mímu rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà. 14Ṣùgbọ́n ó mú pẹpẹ idẹ tí ó wà níwájú Olúwa kúrò láti iwájú ilé náà, láti àárín méjì pẹpẹ náà, àti ilé Olúwa, ó sì fi í sí apá àríwá pẹpẹ náà. 15Ahasi ọba sì pàṣẹ fún Uriah àlùfáà, wí pé, “Lórí pẹpẹ ńlá náà ni kó o máa sun ẹbọ sísun òròwúrọ̀ àti ọrẹ-jíjẹ alaalẹ́, àti ẹbọ sísun ti ọba, àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun tí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọrẹ-jíjẹ wọn, àti ọrẹ ohun mímu wọn; kí o sì wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ sísun náà lórí rẹ̀, àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ mìíràn, ṣùgbọ́n ní ti pẹpẹ idẹ náà èmi ó máa gbèrò ohun tí èmi ó fi ṣe.” 16Báyìí ni Uriah àlùfáà ṣe, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Ahasi ọba pàṣẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.