Native Bible

2 Kings 16:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì sun ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, o si ta ohun mímu rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà.

2 Kings 16:13 in English

2 Kings 16:13 · Berean Standard Bible

He offered his burnt offering and his grain offering, poured out his drink offering, and sprinkled the blood of his peace offerings on the altar.

Context

11Uriah àlùfáà sì kọ́ pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí Ahasi ọba fi ránṣẹ́ sí i láti Damasku; bẹ́ẹ̀ ni Uriah àlùfáà ṣe é dé ìpadàbọ̀ Ahasi ọba láti Damasku. 12Nígbà tí ọba sì ti Damasku dé, ọba sì rí pẹpẹ náà: ọba sì súnmọ́ pẹpẹ náà, ó sì rú ẹbọ lórí rẹ̀. 13Ó sì sun ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, o si ta ohun mímu rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà. 14Ṣùgbọ́n ó mú pẹpẹ idẹ tí ó wà níwájú Olúwa kúrò láti iwájú ilé náà, láti àárín méjì pẹpẹ náà, àti ilé Olúwa, ó sì fi í sí apá àríwá pẹpẹ náà. 15Ahasi ọba sì pàṣẹ fún Uriah àlùfáà, wí pé, “Lórí pẹpẹ ńlá náà ni kó o máa sun ẹbọ sísun òròwúrọ̀ àti ọrẹ-jíjẹ alaalẹ́, àti ẹbọ sísun ti ọba, àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun tí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọrẹ-jíjẹ wọn, àti ọrẹ ohun mímu wọn; kí o sì wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ sísun náà lórí rẹ̀, àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ mìíràn, ṣùgbọ́n ní ti pẹpẹ idẹ náà èmi ó máa gbèrò ohun tí èmi ó fi ṣe.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.