2 Ọba 16:12
2 Kings 16:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ọba sì ti Damasku dé, ọba sì rí pẹpẹ náà: ọba sì súnmọ́ pẹpẹ náà, ó sì rú ẹbọ lórí rẹ̀.
2 Kings 16:12 in English
2 Kings 16:12 · Berean Standard Bible
When the king came back from Damascus and saw the altar, he approached it and presented offerings on it.
Context
10Ọba sì lọ sí Damasku láti pàdé Tiglat-Pileseri, ọba Asiria, ó sì rí pẹpẹ kan tí ó wà ní Damasku: Ahasi ọba sì rán àwòrán pẹpẹ náà, àti àpẹẹrẹ rẹ̀ sí Uriah àlùfáà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo iṣẹ́ ọ̀nà rẹ̀. 11Uriah àlùfáà sì kọ́ pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí Ahasi ọba fi ránṣẹ́ sí i láti Damasku; bẹ́ẹ̀ ni Uriah àlùfáà ṣe é dé ìpadàbọ̀ Ahasi ọba láti Damasku. 12Nígbà tí ọba sì ti Damasku dé, ọba sì rí pẹpẹ náà: ọba sì súnmọ́ pẹpẹ náà, ó sì rú ẹbọ lórí rẹ̀. 13Ó sì sun ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, o si ta ohun mímu rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà. 14Ṣùgbọ́n ó mú pẹpẹ idẹ tí ó wà níwájú Olúwa kúrò láti iwájú ilé náà, láti àárín méjì pẹpẹ náà, àti ilé Olúwa, ó sì fi í sí apá àríwá pẹpẹ náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.