Native Bible

2 Kings 15:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọdún kejìdínlógójì Asariah ọba Juda. Sekariah ọmọ Jeroboamu di ọba Israẹli ní Samaria, ó sì jẹ ọba fún oṣù mẹ́fà.

2 Kings 15:8 in English

2 Kings 15:8 · Berean Standard Bible

In the thirty-eighth year of Azariah’s reign over Judah, Zechariah son of Jeroboam became king of Israel, and he reigned in Samaria six months.

Context

6Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Asariah, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda. 7Asariah sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀. A sì sin ín sí ẹ̀bá wọn ní ìlú ńlá ti Dafidi. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 8Ní ọdún kejìdínlógójì Asariah ọba Juda. Sekariah ọmọ Jeroboamu di ọba Israẹli ní Samaria, ó sì jẹ ọba fún oṣù mẹ́fà. 9Ó ṣe búburú lójú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ tí ṣe. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá. 10Ṣallumu ọmọ Jabesi dìtẹ̀ sí Sekariah. Ó dojúkọ ọ́ níwájú àwọn ènìyàn, ó sì pa á, ó sì jẹ ọba dípò rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.