2 Ọba 15:7
2 Kings 15:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Asariah sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀. A sì sin ín sí ẹ̀bá wọn ní ìlú ńlá ti Dafidi. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
2 Kings 15:7 in English
2 Kings 15:7 · Berean Standard Bible
And Azariah rested with his fathers and was buried near them* in the City of David. And his son Jotham reigned in his place.
Context
5Olúwa sì kọlu ọba náà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀, títí di ọjọ́ tí ó kú, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀tọ̀. Jotamu, ọmọ ọba sì tọ́jú ààfin, ó sì ń darí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. 6Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Asariah, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda. 7Asariah sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀. A sì sin ín sí ẹ̀bá wọn ní ìlú ńlá ti Dafidi. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 8Ní ọdún kejìdínlógójì Asariah ọba Juda. Sekariah ọmọ Jeroboamu di ọba Israẹli ní Samaria, ó sì jẹ ọba fún oṣù mẹ́fà. 9Ó ṣe búburú lójú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ tí ṣe. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.