2 Ọba 15:10
2 Kings 15:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣallumu ọmọ Jabesi dìtẹ̀ sí Sekariah. Ó dojúkọ ọ́ níwájú àwọn ènìyàn, ó sì pa á, ó sì jẹ ọba dípò rẹ̀.
2 Kings 15:10 in English
2 Kings 15:10 · Berean Standard Bible
Then Shallum son of Jabesh conspired against Zechariah, struck him down and killed him in front of the people,* and reigned in his place.
Context
8Ní ọdún kejìdínlógójì Asariah ọba Juda. Sekariah ọmọ Jeroboamu di ọba Israẹli ní Samaria, ó sì jẹ ọba fún oṣù mẹ́fà. 9Ó ṣe búburú lójú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ tí ṣe. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá. 10Ṣallumu ọmọ Jabesi dìtẹ̀ sí Sekariah. Ó dojúkọ ọ́ níwájú àwọn ènìyàn, ó sì pa á, ó sì jẹ ọba dípò rẹ̀. 11Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Sekariah. Wọ́n kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli. 12Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ fún Jehu jẹ́ ìmúṣẹ: “Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Israẹli títí dé ìran kẹrin.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.