Native Bible

2 Kings 13:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jehoahasi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín sí Samaria. Jehoaṣi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

2 Kings 13:9 in English

2 Kings 13:9 · Berean Standard Bible

And Jehoahaz rested with his fathers and was buried in Samaria. And his son Jehoash * reigned in his place.

Context

7Kò sí ohùn kan tí wọ́n fi sílẹ̀ ní ti ọmọ-ogun Jehoahasi àyàfi àádọ́ta ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, kẹ̀kẹ́ mẹ́wàá, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣẹ̀, nítorí ọba Siria ti pa ìyókù run, ó sì ṣe wọ́n bí eruku nígbà pípa ọkà. 8Fún ti ìyókù ìṣe Jehoahasi fún ìgbà, tí ó fi jẹ ọba, gbogbo ohun tí ó ṣe àti àṣeyọrí rẹ̀ ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli? 9Jehoahasi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín sí Samaria. Jehoaṣi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 10Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí Joaṣi ọba Juda, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi di ọba Israẹli ní Samaria ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́rìndínlógún. 11Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati èyí tí ó ti ti Israẹli láti fà. Ó sì tẹ̀síwájú nínú wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.