2 Ọba 13:10
2 Kings 13:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí Joaṣi ọba Juda, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi di ọba Israẹli ní Samaria ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́rìndínlógún.
2 Kings 13:10 in English
2 Kings 13:10 · Berean Standard Bible
In the thirty-seventh year of the reign of Joash over Judah, Jehoash son of Jehoahaz became king of Israel in Samaria, and he reigned sixteen years.
Context
8Fún ti ìyókù ìṣe Jehoahasi fún ìgbà, tí ó fi jẹ ọba, gbogbo ohun tí ó ṣe àti àṣeyọrí rẹ̀ ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli? 9Jehoahasi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín sí Samaria. Jehoaṣi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 10Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí Joaṣi ọba Juda, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi di ọba Israẹli ní Samaria ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́rìndínlógún. 11Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati èyí tí ó ti ti Israẹli láti fà. Ó sì tẹ̀síwájú nínú wọn. 12Fún ti ìyókù iṣẹ́ Jehoaṣi fún ìgbà tí ó fi jẹ ọba, gbogbo ohun tí ó ṣe, pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀ pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Amasiah ọba Juda, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.