Native Bible

2 Corinthians 12:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi ha rẹ́ yín jẹ nípa ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí mo rán sí yín bi?

2 Corinthians 12:17 in English

2 Corinthians 12:17 · Berean Standard Bible

Did I exploit you by anyone I sent you?

Context

15Èmi ó sì fi ayọ̀ ná ohun gbogbo tí mo bá ní, èmi ó sì ná ara mi fún ọkàn yín nítòótọ́; bí mo bá fẹ́ yín lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ó ha tọ́ kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn mi díẹ̀ bí? 16Ṣùgbọ́n ó dára bẹ́ẹ̀ tí èmi kò dẹ́rùbà yín, ṣùgbọ́n bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, èmi ń fi ọwọ́ ẹ̀rọ̀ mú yín. 17Èmi ha rẹ́ yín jẹ nípa ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí mo rán sí yín bi? 18Mo bẹ Titu, mo sì rán arákùnrin kan pẹ̀lú rẹ̀; Titu ha rẹ́ yín jẹ bí? Nípa ẹ̀mí kan náà kọ́ ni àwa rìn bí? Ọ̀nà kan náà kọ́ ni àwa tọ̀ bí? 19Ẹ̀yin ha rò pé àwa ń sọ nǹkan wọ̀nyí láti gbèjà ara wa níwájú yín bí? Ní iwájú Ọlọ́run ni àwa ń sọ̀rọ̀ nínú Kristi; ṣùgbọ́n àwa ń ṣe ohun gbogbo, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, láti gbé yín ró ni.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.