2 Kọrinti 12:15
2 Corinthians 12:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi ó sì fi ayọ̀ ná ohun gbogbo tí mo bá ní, èmi ó sì ná ara mi fún ọkàn yín nítòótọ́; bí mo bá fẹ́ yín lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ó ha tọ́ kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn mi díẹ̀ bí?
2 Corinthians 12:15 in English
2 Corinthians 12:15 · Berean Standard Bible
And for the sake of your souls, I will most gladly spend my money and myself. If I love you more, will you love me less?
Context
13Nítorí nínú kín ni ohun tí ẹ̀yin ṣe rẹ̀yìn sí ìjọ mìíràn, bí kò ṣe ní ti pé èmi fúnra mi kó jẹ́ oníyọnu fún yín? Ẹ dárí àṣìṣe yìí jì mí. 14Kíyèsi i, ìgbà kẹta yìí ni mo múra tan láti tọ̀ yín wá, èmi kì yóò sì jẹ́ oníyọnu fún yín nítorí tí èmi kò wá nǹkan yín, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnra yín; nítorí tí kò tọ́ fún àwọn ọmọ láti máa to ìṣúra jọ fún àwọn òbí wọn, bí kò ṣe àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn. 15Èmi ó sì fi ayọ̀ ná ohun gbogbo tí mo bá ní, èmi ó sì ná ara mi fún ọkàn yín nítòótọ́; bí mo bá fẹ́ yín lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ó ha tọ́ kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn mi díẹ̀ bí? 16Ṣùgbọ́n ó dára bẹ́ẹ̀ tí èmi kò dẹ́rùbà yín, ṣùgbọ́n bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, èmi ń fi ọwọ́ ẹ̀rọ̀ mú yín. 17Èmi ha rẹ́ yín jẹ nípa ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí mo rán sí yín bi?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.