Native Bible

2 Chronicles 6:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni ó sì wí pé: “Ògo ni fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ mú ohun tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dafidi baba mi ṣẹ. Nítorí tí ó wí pé,

2 Chronicles 6:4 in English

2 Chronicles 6:4 · Berean Standard Bible

and said: “Blessed be the LORD, the God of Israel, who has fulfilled with His own hand what He spoke with His mouth to my father David, saying,

Context

2ṣùgbọ́n èmi ti kọ́ tẹmpili dáradára fún ọ ibi tí ìwọ yóò máa gbé títí láé.” 3Ní ìgbà tí gbogbo ìjọ Israẹli dúró níbẹ̀, ọba yíjú padà ó sì fi ìbùkún fún gbogbo wọn. 4Nígbà náà ni ó sì wí pé: “Ògo ni fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ mú ohun tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dafidi baba mi ṣẹ. Nítorí tí ó wí pé, 5‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, èmi kò yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli, láti kọ́ ilé, kí orúkọ mi kí ó lè wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yan ẹnikẹ́ni láti jẹ́ olórí lórí Israẹli ènìyàn mi. 6Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ti yan Jerusalẹmu, kí orúkọ mi le è wà níbẹ̀, èmi sì ti yan Dafidi láti jẹ ọba lórí Israẹli ènìyàn mi.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.