Native Bible

2 Chronicles 6:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ìgbà tí gbogbo ìjọ Israẹli dúró níbẹ̀, ọba yíjú padà ó sì fi ìbùkún fún gbogbo wọn.

2 Chronicles 6:3 in English

2 Chronicles 6:3 · Berean Standard Bible

And as the whole assembly of Israel stood there, the king turned around and blessed them all

Context

1Nígbà náà ni Solomoni wí pé, “Olúwa ti sọ wí pé òun yóò máa gbé nínú òkùnkùn tí ó ṣú biribiri; 2ṣùgbọ́n èmi ti kọ́ tẹmpili dáradára fún ọ ibi tí ìwọ yóò máa gbé títí láé.” 3Ní ìgbà tí gbogbo ìjọ Israẹli dúró níbẹ̀, ọba yíjú padà ó sì fi ìbùkún fún gbogbo wọn. 4Nígbà náà ni ó sì wí pé: “Ògo ni fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ mú ohun tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dafidi baba mi ṣẹ. Nítorí tí ó wí pé, 5‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, èmi kò yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli, láti kọ́ ilé, kí orúkọ mi kí ó lè wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yan ẹnikẹ́ni láti jẹ́ olórí lórí Israẹli ènìyàn mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.