Native Bible

2 Chronicles 35:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn akọrin, àwọn ọmọ Asafu, ni wọ́n wà ní ipò wọn tí a sì paláṣẹ fún wọn láti ọwọ́ Dafidi, Asafu, Hemani àti Jedutuni àwọn aríran ọba àti àwọn olùṣọ́nà ní olúkúlùkù ẹnu-ọ̀nà kò gbọdọ̀ fi ojú ọ̀nà wọn sílẹ̀, nítorí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ lefi ti múra sílẹ̀ fún wọn.

2 Chronicles 35:15 in English

2 Chronicles 35:15 · Berean Standard Bible

The singers, the descendants of Asaph, were at their stations according to the command of David, Asaph, Heman, and Jeduthun the king’s seer. And the gatekeepers at each gate did not need to leave their position, because their fellow Levites made preparations for them.

Context

13Wọ́n sì fi sun àjọ ìrékọjá lórí iná gẹ́gẹ́ bí ìlànà, wọ́n sì bọ ẹbọ mímọ́ nínú ìkòkò, nínú ọpọ́n àti nínú agbada, wọ́n sì pín wọn kíákíá fún gbogbo àwọn ènìyàn. 14Lẹ́yìn èyí, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn àlùfáà nítorí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Aaroni, ni wọ́n rú ẹbọ sísun àti ọ̀rá títí di àṣálẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ Aaroni àlùfáà. 15Àwọn akọrin, àwọn ọmọ Asafu, ni wọ́n wà ní ipò wọn tí a sì paláṣẹ fún wọn láti ọwọ́ Dafidi, Asafu, Hemani àti Jedutuni àwọn aríran ọba àti àwọn olùṣọ́nà ní olúkúlùkù ẹnu-ọ̀nà kò gbọdọ̀ fi ojú ọ̀nà wọn sílẹ̀, nítorí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ lefi ti múra sílẹ̀ fún wọn. 16Bẹ́ẹ̀ ni àsìkò náà gbogbo àwọn ìsìn Olúwa ni wọ́n gbé jáde fún iṣẹ́ ìrántí àjọ ìrékọjá àti láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ọba Josiah ti pa á láṣẹ. 17Àwọn ọmọ Israẹli tí ó gbé kalẹ̀ ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá ní àkókò náà àti àjọ àkàrà àìwú fún ọjọ́ méje.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.