Native Bible

2 Chronicles 35:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni àsìkò náà gbogbo àwọn ìsìn Olúwa ni wọ́n gbé jáde fún iṣẹ́ ìrántí àjọ ìrékọjá àti láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ọba Josiah ti pa á láṣẹ.

2 Chronicles 35:16 in English

2 Chronicles 35:16 · Berean Standard Bible

So on that day the entire service of the LORD was carried out for celebrating the Passover and offering burnt offerings on the altar of the LORD, according to the command of King Josiah.

Context

14Lẹ́yìn èyí, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn àlùfáà nítorí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Aaroni, ni wọ́n rú ẹbọ sísun àti ọ̀rá títí di àṣálẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ Aaroni àlùfáà. 15Àwọn akọrin, àwọn ọmọ Asafu, ni wọ́n wà ní ipò wọn tí a sì paláṣẹ fún wọn láti ọwọ́ Dafidi, Asafu, Hemani àti Jedutuni àwọn aríran ọba àti àwọn olùṣọ́nà ní olúkúlùkù ẹnu-ọ̀nà kò gbọdọ̀ fi ojú ọ̀nà wọn sílẹ̀, nítorí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ lefi ti múra sílẹ̀ fún wọn. 16Bẹ́ẹ̀ ni àsìkò náà gbogbo àwọn ìsìn Olúwa ni wọ́n gbé jáde fún iṣẹ́ ìrántí àjọ ìrékọjá àti láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ọba Josiah ti pa á láṣẹ. 17Àwọn ọmọ Israẹli tí ó gbé kalẹ̀ ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá ní àkókò náà àti àjọ àkàrà àìwú fún ọjọ́ méje. 18Àjọ ìrékọjá náà kò sì tí ì sí èyí tí ó dàbí i rẹ̀ ní Israẹli títí dé ọjọ́ wòlíì Samuẹli, kò sì sí ọ̀kan lára àwọn ọba Israẹli tí ó pa irú àjọ ìrékọjá bẹ́ẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Josiah ti ṣe, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àwọn ọmọ Lefi àti gbogbo àwọn Juda àti Israẹli tí ó wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.