2 Kronika 35:17
2 Chronicles 35:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọmọ Israẹli tí ó gbé kalẹ̀ ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá ní àkókò náà àti àjọ àkàrà àìwú fún ọjọ́ méje.
2 Chronicles 35:17 in English
2 Chronicles 35:17 · Berean Standard Bible
The Israelites who were present also observed the Passover at that time, as well as the Feast of Unleavened Bread * for seven days.
Context
15Àwọn akọrin, àwọn ọmọ Asafu, ni wọ́n wà ní ipò wọn tí a sì paláṣẹ fún wọn láti ọwọ́ Dafidi, Asafu, Hemani àti Jedutuni àwọn aríran ọba àti àwọn olùṣọ́nà ní olúkúlùkù ẹnu-ọ̀nà kò gbọdọ̀ fi ojú ọ̀nà wọn sílẹ̀, nítorí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ lefi ti múra sílẹ̀ fún wọn. 16Bẹ́ẹ̀ ni àsìkò náà gbogbo àwọn ìsìn Olúwa ni wọ́n gbé jáde fún iṣẹ́ ìrántí àjọ ìrékọjá àti láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ọba Josiah ti pa á láṣẹ. 17Àwọn ọmọ Israẹli tí ó gbé kalẹ̀ ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá ní àkókò náà àti àjọ àkàrà àìwú fún ọjọ́ méje. 18Àjọ ìrékọjá náà kò sì tí ì sí èyí tí ó dàbí i rẹ̀ ní Israẹli títí dé ọjọ́ wòlíì Samuẹli, kò sì sí ọ̀kan lára àwọn ọba Israẹli tí ó pa irú àjọ ìrékọjá bẹ́ẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Josiah ti ṣe, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àwọn ọmọ Lefi àti gbogbo àwọn Juda àti Israẹli tí ó wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu. 19Àjọ ìrékọjá yìí ni a ṣe ìrántí ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Josiah.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.