Native Bible

2 Chronicles 31:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Hesekiah àti àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá, tí wọ́n sì rí òkìtì náà, wọ́n yin Olúwa, pẹ̀lú ìbùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli.

2 Chronicles 31:8 in English

2 Chronicles 31:8 · Berean Standard Bible

When Hezekiah and his officials came and viewed the heaps, they blessed the LORD and His people Israel.

Context

6Àwọn ọkùnrin Israẹli àti Juda ti gbe inú àwọn ìlú Juda pẹ̀lú mú ìdámẹ́wàá agbo ẹran àti ohun èlò àti ohun ọ̀sìn àti ìdámẹ́wàá ti àwọn nǹkan mímọ́ tí a ti yà sọ́tọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì kó wọn jọ ní òkìtì. 7Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe èyí ní oṣù kẹta, wọ́n sì parí ní oṣù keje. 8Nígbà tí Hesekiah àti àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá, tí wọ́n sì rí òkìtì náà, wọ́n yin Olúwa, pẹ̀lú ìbùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli. 9Hesekiah béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi nípa òkìtì; 10àti Asariah olórí àlùfáà ti ìdílé Sadoku sì dáhùn pé, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní mú ìdáwó wọn wá sí ilé Olúwa àti ní èyí tí yóò tó jẹ àti ọ̀pọ̀ láti tọ́jú pamọ́ nítorí Olúwa ti bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ṣẹ́kù lọ́pọ̀lọ́pọ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.