Native Bible

2 Chronicles 31:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

àti Asariah olórí àlùfáà ti ìdílé Sadoku sì dáhùn pé, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní mú ìdáwó wọn wá sí ilé Olúwa àti ní èyí tí yóò tó jẹ àti ọ̀pọ̀ láti tọ́jú pamọ́ nítorí Olúwa ti bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ṣẹ́kù lọ́pọ̀lọ́pọ̀.”

2 Chronicles 31:10 in English

2 Chronicles 31:10 · Berean Standard Bible

and Azariah, the chief priest of the household of Zadok, answered him, “Since the people began to bring their contributions into the house of the LORD, we have had enough to eat and there is plenty left over, because the LORD has blessed His people; this great abundance is what is left over.”

Context

8Nígbà tí Hesekiah àti àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá, tí wọ́n sì rí òkìtì náà, wọ́n yin Olúwa, pẹ̀lú ìbùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli. 9Hesekiah béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi nípa òkìtì; 10àti Asariah olórí àlùfáà ti ìdílé Sadoku sì dáhùn pé, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní mú ìdáwó wọn wá sí ilé Olúwa àti ní èyí tí yóò tó jẹ àti ọ̀pọ̀ láti tọ́jú pamọ́ nítorí Olúwa ti bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ṣẹ́kù lọ́pọ̀lọ́pọ̀.” 11Hesekiah pàṣẹ láti tọ́jú àwọn yàrá ìṣúra nínú ilé Olúwa, wọ́n sì ṣe èyí. 12Nígbà náà wọ́n mú ọrẹ àti ìdámẹ́wàá àti àwọn ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ wọ ilé náà wá nítòótọ́. Lórí èyí tí Konaniah ọmọ Lefi, ń ṣe olórí, Ṣimei arákùnrin rẹ̀ ni igbákejì rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.