2 Kronika 31:6
2 Chronicles 31:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọkùnrin Israẹli àti Juda ti gbe inú àwọn ìlú Juda pẹ̀lú mú ìdámẹ́wàá agbo ẹran àti ohun èlò àti ohun ọ̀sìn àti ìdámẹ́wàá ti àwọn nǹkan mímọ́ tí a ti yà sọ́tọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì kó wọn jọ ní òkìtì.
2 Chronicles 31:6 in English
2 Chronicles 31:6 · Berean Standard Bible
And the Israelites and Judahites who lived in the cities of Judah also brought a tithe of their herds and flocks and a tithe of the holy things consecrated to the LORD their God, and they laid them in large heaps.
Context
4Ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu láti fi ìpín tí ó yẹ fún àlùfáà fún un àti àwọn ará Lefi, kí wọn kí ó lè fi ara wọn jì fún òfin Olúwa. 5Ní kété tí àṣẹ náà jáde lọ, àwọn ọmọ Israẹli fi tìfẹ́tìfẹ́ fi àkọ́so ti ọkà wọn, ọtí tuntun, òróró àti oyin àti gbogbo ohun tí pápá mú jáde lélẹ̀. Wọ́n kó ọ̀pọ̀ iye, àti ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan wá. 6Àwọn ọkùnrin Israẹli àti Juda ti gbe inú àwọn ìlú Juda pẹ̀lú mú ìdámẹ́wàá agbo ẹran àti ohun èlò àti ohun ọ̀sìn àti ìdámẹ́wàá ti àwọn nǹkan mímọ́ tí a ti yà sọ́tọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì kó wọn jọ ní òkìtì. 7Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe èyí ní oṣù kẹta, wọ́n sì parí ní oṣù keje. 8Nígbà tí Hesekiah àti àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá, tí wọ́n sì rí òkìtì náà, wọ́n yin Olúwa, pẹ̀lú ìbùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.