Native Bible

2 Chronicles 31:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní kété tí àṣẹ náà jáde lọ, àwọn ọmọ Israẹli fi tìfẹ́tìfẹ́ fi àkọ́so ti ọkà wọn, ọtí tuntun, òróró àti oyin àti gbogbo ohun tí pápá mú jáde lélẹ̀. Wọ́n kó ọ̀pọ̀ iye, àti ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan wá.

2 Chronicles 31:5 in English

2 Chronicles 31:5 · Berean Standard Bible

As soon as the order went out, the Israelites generously provided the firstfruits of the grain, new wine, oil, and honey, and of all the produce of the field, and they brought in an abundance—a tithe of everything.

Context

3Ọba fi sílẹ̀ láti ara ohun ìní rẹ̀ fun ẹbọ sísun àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti fún ẹbọ sísun ní ọjọ́ ìsinmi, òṣùpá tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn gẹ́gẹ́ bi a ti ṣe kọ ọ́ nínú òfin Olúwa. 4Ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu láti fi ìpín tí ó yẹ fún àlùfáà fún un àti àwọn ará Lefi, kí wọn kí ó lè fi ara wọn jì fún òfin Olúwa. 5Ní kété tí àṣẹ náà jáde lọ, àwọn ọmọ Israẹli fi tìfẹ́tìfẹ́ fi àkọ́so ti ọkà wọn, ọtí tuntun, òróró àti oyin àti gbogbo ohun tí pápá mú jáde lélẹ̀. Wọ́n kó ọ̀pọ̀ iye, àti ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan wá. 6Àwọn ọkùnrin Israẹli àti Juda ti gbe inú àwọn ìlú Juda pẹ̀lú mú ìdámẹ́wàá agbo ẹran àti ohun èlò àti ohun ọ̀sìn àti ìdámẹ́wàá ti àwọn nǹkan mímọ́ tí a ti yà sọ́tọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì kó wọn jọ ní òkìtì. 7Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe èyí ní oṣù kẹta, wọ́n sì parí ní oṣù keje.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.