Native Bible

2 Chronicles 29:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọmọ mi, ẹ má ṣe jáfara nísinsin yìí, nítorí tí Olúwa ti yàn yín láti dúró níwájú rẹ̀ láti sin, kí ẹ sì máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti sun tùràrí.”

2 Chronicles 29:11 in English

2 Chronicles 29:11 · Berean Standard Bible

Now, my sons, do not be negligent, for the LORD has chosen you to stand before Him, to serve Him, to minister before Him, and to burn incense.”

Context

9Ìdí nìyí tí àwọn baba wa ṣe ṣubú nípa idà àti ìdí tí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin àti àwọn aya wa tiwọn kó wọ́n ní ìgbèkùn. 10Nísinsin yìí ó wà ní ọkàn mi láti bá Olúwa Ọlọ́run Israẹli dá májẹ̀mú. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìbínú rẹ̀ kíkan kí ó lè yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa. 11Àwọn ọmọ mi, ẹ má ṣe jáfara nísinsin yìí, nítorí tí Olúwa ti yàn yín láti dúró níwájú rẹ̀ láti sin, kí ẹ sì máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti sun tùràrí.” 12Nígbà náà àwọn ọmọ Lefi wọ̀nyí múra láti ṣe iṣẹ́: nínú àwọn ọmọ Kohati, Mahati ọmọ Amasai: àti Joẹli ọmọ Asariah; nínú àwọn ọmọ Merari, Kiṣi ọmọ Abdi àti Asariah ọmọ Jehaleeli; nínú àwọn ọmọ Gerṣoni, Joah, ọmọ Simma àti Edeni ọmọ Joah; 13nínú àwọn ọmọ Elisafani, Ṣimri àti Jeieli; nínú àwọn ọmọ Asafu, Sekariah àti Mattaniah;

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.