Native Bible

2 Chronicles 18:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nísinsin yìí ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ má ṣe jà pẹ̀lú ẹnìkankan, èwe tàbí àgbà àyàfi ọba Israẹli.”

2 Chronicles 18:30 in English

2 Chronicles 18:30 · Berean Standard Bible

Now the king of Aram had ordered his chariot commanders, “Do not fight with anyone, small or great, except the king of Israel.”

Context

28Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda lọ sókè ní Ramoti Gileadi. 29Ọba Israẹli sọ fún Jehoṣafati pé, “Èmi yóò lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli pa aṣọ rẹ̀ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà. 30Nísinsin yìí ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ má ṣe jà pẹ̀lú ẹnìkankan, èwe tàbí àgbà àyàfi ọba Israẹli.” 31Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rí Jehoṣafati, wọ́n rò wí pé, “Èyí ní ọba Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yípadà láti bá a jà. Ṣùgbọ́n Jehoṣafati kégbe sókè, Olúwa sì ràn án lọ́wọ́. Ọlọ́run sì lé wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, 32Ó sì ṣe, nígbà tí olórí kẹ̀kẹ́ rí i wí pé kì í ṣe ọba Israẹli, wọ́n sì dáwọ́ lílé rẹ̀ dúró.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.