Native Bible

2 Chronicles 18:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda lọ sókè ní Ramoti Gileadi.

2 Chronicles 18:28 in English

2 Chronicles 18:28 · Berean Standard Bible

So the king of Israel and Jehoshaphat king of Judah went up to Ramoth-gilead.

Context

26Ó sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí ọba sọ, ẹ fi ènìyàn yìí sínú túbú kí ẹ má sì ṣe fún un ní ohunkóhun ṣùgbọ́n àkàrà àti omi títí tí èmi yóò fi dé ní àlàáfíà.’ ” 27Mikaiah sì wí pe, “Tí ìwọ bá padà ní àlàáfíà, Olúwa kò sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà náà, ó sì fi kún un pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn!” 28Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda lọ sókè ní Ramoti Gileadi. 29Ọba Israẹli sọ fún Jehoṣafati pé, “Èmi yóò lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli pa aṣọ rẹ̀ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà. 30Nísinsin yìí ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ má ṣe jà pẹ̀lú ẹnìkankan, èwe tàbí àgbà àyàfi ọba Israẹli.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.