Native Bible

2 Chronicles 17:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èkejì, Jehohanani olórí, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá (280,000) ọkùnrin;

2 Chronicles 17:15 in English

2 Chronicles 17:15 · Berean Standard Bible

next to him, Jehohanan the commander, and with him 280,000;

Context

13Ó sì ní ìṣúra ní ìlú Juda. Ó sì tún ní àwọn alágbára jagunjagun akọni ọkùnrin ní Jerusalẹmu. 14Iye wọn gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn nìwọ̀nyí. Láti Juda, àwọn olórí ìpín kan ti ẹgbẹ̀rún (1,000): Adina olórí, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) alágbára akọni ọkùnrin. 15Èkejì, Jehohanani olórí, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá (280,000) ọkùnrin; 16àtẹ̀lé Amasiah ọmọ Sikri, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ Olúwa pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000). 17Láti ọ̀dọ̀ Benjamini: Eliada, alágbára akọni ọkùnrin pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn jagunjagun ọkùnrin pẹ̀lú ọrun àti àpáta ìhámọ́ra;

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.