Native Bible

2 Chronicles 12:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu, ó gbé àwọn ìṣúra ilé Olúwa, àti àwọn ìṣúra ààfin ọba. Ó gbé gbogbo rẹ̀, pẹ̀lú àwọn àpáta wúrà tí Solomoni dá.

2 Chronicles 12:9 in English

2 Chronicles 12:9 · Berean Standard Bible

So King Shishak of Egypt attacked Jerusalem and seized the treasures of the house of the LORD and of the royal palace. He took everything, including the gold shields that Solomon had made.

Context

7Nígbà tí Olúwa rí i pé, wọ́n ti rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa yí tọ Ṣemaiah lọ pé, “Níwọ́n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, Èmi kì yóò pa wọ́n ṣùgbọ́n, yóò fún wọn ní ìtúsílẹ̀ tó bá yá. Ìbínú mi kì yóò dà sórí Jerusalẹmu ní ipasẹ̀ Ṣiṣaki. 8Bí ó ti wù kí ó rí, wọn yóò sìn ní abẹ́ rẹ̀, kí wọn kí ó lè mọ̀ ìyàtọ̀ láàrín sí sìn mí àti sí sin àwọn ọba ilẹ̀ mìíràn.” 9Nígbà tí Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu, ó gbé àwọn ìṣúra ilé Olúwa, àti àwọn ìṣúra ààfin ọba. Ó gbé gbogbo rẹ̀, pẹ̀lú àwọn àpáta wúrà tí Solomoni dá. 10Bẹ́ẹ̀ ni, ọba Rehoboamu dá àwọn àpáta idẹ láti fi dípò wọn, ó sì fi èyí lé àwọn alákòóso àti olùṣọ́ tí ó wà ní ẹnu iṣẹ́ ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ààfin ọba lọ́wọ́. 11Ìgbàkígbà tí ọba bá lọ sí ilé Olúwa, àwọn olùṣọ́ n lọ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n ń gbé àwọn àpáta náà àti lẹ́yìn, wọ́n dá wọn padà sí yàrá ìṣọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.