Native Bible

2 Chronicles 12:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìgbàkígbà tí ọba bá lọ sí ilé Olúwa, àwọn olùṣọ́ n lọ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n ń gbé àwọn àpáta náà àti lẹ́yìn, wọ́n dá wọn padà sí yàrá ìṣọ́.

2 Chronicles 12:11 in English

2 Chronicles 12:11 · Berean Standard Bible

And whenever the king entered the house of the LORD, the guards would go with him, bearing the shields, and later they would return them to the guardroom.

Context

9Nígbà tí Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu, ó gbé àwọn ìṣúra ilé Olúwa, àti àwọn ìṣúra ààfin ọba. Ó gbé gbogbo rẹ̀, pẹ̀lú àwọn àpáta wúrà tí Solomoni dá. 10Bẹ́ẹ̀ ni, ọba Rehoboamu dá àwọn àpáta idẹ láti fi dípò wọn, ó sì fi èyí lé àwọn alákòóso àti olùṣọ́ tí ó wà ní ẹnu iṣẹ́ ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ààfin ọba lọ́wọ́. 11Ìgbàkígbà tí ọba bá lọ sí ilé Olúwa, àwọn olùṣọ́ n lọ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n ń gbé àwọn àpáta náà àti lẹ́yìn, wọ́n dá wọn padà sí yàrá ìṣọ́. 12Nítorí ti Rehoboamu rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ìbínú Olúwa yí padà kúrò lórí rẹ̀, a kò sì pa á run pátápátá. Nítòótọ́, ìre díẹ̀ wà ní Juda. 13Ọba Rehoboamu fi ara rẹ̀ lélẹ̀ gidigidi ní Jerusalẹmu, ó sì tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí ọba. Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógójì nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu, ìlú ńlá tí Olúwa ti yàn jáde kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli ní èyí tí ó fẹ́ fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Naama, ará Ammoni.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.