2 Kronika 12:7
2 Chronicles 12:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Olúwa rí i pé, wọ́n ti rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa yí tọ Ṣemaiah lọ pé, “Níwọ́n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, Èmi kì yóò pa wọ́n ṣùgbọ́n, yóò fún wọn ní ìtúsílẹ̀ tó bá yá. Ìbínú mi kì yóò dà sórí Jerusalẹmu ní ipasẹ̀ Ṣiṣaki.
2 Chronicles 12:7 in English
2 Chronicles 12:7 · Berean Standard Bible
When the LORD saw that they had humbled themselves, the word of the LORD came to Shemaiah, saying, “They have humbled themselves; I will not destroy them, but will soon grant them deliverance. My wrath will not be poured out on Jerusalem through Shishak.
Context
5Nígbà náà, wòlíì Ṣemaiah wá sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí Juda tí wọ́n ti péjọ ní Jerusalẹmu nítorí ìbẹ̀rù Ṣiṣaki, ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ìwọ ti pa mí tì; nítorí náà èmi náà ti pa yín tì sí ọ̀dọ̀ Ṣiṣaki.” 6Àwọn olórí Israẹli àti ọba rẹ̀ ará wọn sílẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Olódodo ni Olúwa.” 7Nígbà tí Olúwa rí i pé, wọ́n ti rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa yí tọ Ṣemaiah lọ pé, “Níwọ́n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, Èmi kì yóò pa wọ́n ṣùgbọ́n, yóò fún wọn ní ìtúsílẹ̀ tó bá yá. Ìbínú mi kì yóò dà sórí Jerusalẹmu ní ipasẹ̀ Ṣiṣaki. 8Bí ó ti wù kí ó rí, wọn yóò sìn ní abẹ́ rẹ̀, kí wọn kí ó lè mọ̀ ìyàtọ̀ láàrín sí sìn mí àti sí sin àwọn ọba ilẹ̀ mìíràn.” 9Nígbà tí Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu, ó gbé àwọn ìṣúra ilé Olúwa, àti àwọn ìṣúra ààfin ọba. Ó gbé gbogbo rẹ̀, pẹ̀lú àwọn àpáta wúrà tí Solomoni dá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.