Native Bible

2 Chronicles 10:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́mọdé, ó sì wí pé, “Baba mi mú kí àjàgà yín wúwo; èmi yóò sì mú kí ó wúwo jù bẹ́ẹ̀ lọ. Baba mi nà yín pẹ̀lú pàṣán; èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe.”

2 Chronicles 10:14 in English

2 Chronicles 10:14 · Berean Standard Bible

and spoke to them as the young men had advised, saying, “Whereas my father made your yoke heavy,* I will add to your yoke. Whereas my father scourged you with whips, I will scourge you with scorpions.”

Context

12Ní ọjọ́ kẹta Jeroboamu àti gbogbo ènìyàn sì padà sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu, gẹ́gẹ́ bí ọba ti sọ, “Ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ kẹta.” 13Nígbà náà ni ọba dá wọn lóhùn ní ọ̀nà líle. Rehoboamu ọba sì kọ̀ ìmọ̀ràn àwọn àgbàgbà sílẹ̀, 14Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́mọdé, ó sì wí pé, “Baba mi mú kí àjàgà yín wúwo; èmi yóò sì mú kí ó wúwo jù bẹ́ẹ̀ lọ. Baba mi nà yín pẹ̀lú pàṣán; èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe.” 15Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì fetísí àwọn ènìyàn, nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni. Láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ tí a ti sọ fún Jeroboamu ọmọ Nebati nípasẹ̀ Ahijah ará Ṣilo. 16Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i wí pé ọba kọ̀ láti gbọ́ tiwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn wí pé, “Ìpín kí ní a ní nínú Dafidi, ìní wo ni a ní nínú ọmọ Jese? Ẹ lọ sí àgọ́ yín, ẹ̀yin Israẹli! Bojútó ilé rẹ, ìwọ Dafidi!” Bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ilé wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.