Native Bible

2 Chronicles 10:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ kẹta Jeroboamu àti gbogbo ènìyàn sì padà sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu, gẹ́gẹ́ bí ọba ti sọ, “Ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ kẹta.”

2 Chronicles 10:12 in English

2 Chronicles 10:12 · Berean Standard Bible

After three days, Jeroboam and all the people returned to Rehoboam, since the king had said, “Come back to me on the third day.”

Context

10Àwọn ọ̀dọ́mọdé tí ó ti dàgbà pẹ̀lú rẹ dá a lóhùn pé, “Sọ fún àwọn ènìyàn tí ó wí fún ọ wí pé, ‘Baba rẹ gbé àjàgà wúwo lórí wa, ṣùgbọ́n mú àjàgà wa fúyẹ́,’ wí fún wọn pé, ‘Ìka ọwọ́ mi kékeré, ó nípọn ju ìbàdí baba mi lọ. 11Baba mi gbé àjàgà wúwo ka orí yín; èmi yóò sì tún mú kí ó wúwo sì í. Baba mi fi pàṣán nà yín; èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe.’ ” 12Ní ọjọ́ kẹta Jeroboamu àti gbogbo ènìyàn sì padà sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu, gẹ́gẹ́ bí ọba ti sọ, “Ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ kẹta.” 13Nígbà náà ni ọba dá wọn lóhùn ní ọ̀nà líle. Rehoboamu ọba sì kọ̀ ìmọ̀ràn àwọn àgbàgbà sílẹ̀, 14Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́mọdé, ó sì wí pé, “Baba mi mú kí àjàgà yín wúwo; èmi yóò sì mú kí ó wúwo jù bẹ́ẹ̀ lọ. Baba mi nà yín pẹ̀lú pàṣán; èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.