Native Bible

2 Chronicles 10:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i wí pé ọba kọ̀ láti gbọ́ tiwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn wí pé, “Ìpín kí ní a ní nínú Dafidi, ìní wo ni a ní nínú ọmọ Jese? Ẹ lọ sí àgọ́ yín, ẹ̀yin Israẹli! Bojútó ilé rẹ, ìwọ Dafidi!” Bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ilé wọn.

2 Chronicles 10:16 in English

2 Chronicles 10:16 · Berean Standard Bible

When all Israel saw that the king had refused to listen to them, they answered * the king: “What portion do we have in David, and what inheritance in the son of Jesse? To your tents, O Israel! Look now to your own house, O David!” So all the Israelites went home,

Context

14Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́mọdé, ó sì wí pé, “Baba mi mú kí àjàgà yín wúwo; èmi yóò sì mú kí ó wúwo jù bẹ́ẹ̀ lọ. Baba mi nà yín pẹ̀lú pàṣán; èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe.” 15Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì fetísí àwọn ènìyàn, nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni. Láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ tí a ti sọ fún Jeroboamu ọmọ Nebati nípasẹ̀ Ahijah ará Ṣilo. 16Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i wí pé ọba kọ̀ láti gbọ́ tiwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn wí pé, “Ìpín kí ní a ní nínú Dafidi, ìní wo ni a ní nínú ọmọ Jese? Ẹ lọ sí àgọ́ yín, ẹ̀yin Israẹli! Bojútó ilé rẹ, ìwọ Dafidi!” Bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ilé wọn. 17Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé ní ìlú Juda, Rehoboamu ń jẹ ọba lórí wọn. 18Ọba Rehoboamu rán Adoniramu jáde, ẹni tí ó wà ní ìkáwọ́ iṣẹ́ onírúurú, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa. Ọba Rehoboamu, gbìyànjú láti dé inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì sálọ sí Jerusalẹmu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.