1 Timotiu 5:19
1 Timothy 5:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Má ṣe gba ẹ̀sùn sí alàgbà kan, bí kò ṣe láti ẹnu ẹlẹ́rìí méjì mẹ́ta.
1 Timothy 5:19 in English
1 Timothy 5:19 · Berean Standard Bible
Do not entertain an accusation against an elder, except on the testimony of two or three witnesses.
Context
17Àwọn alàgbà ti ó ṣe àkóso dáradára ni kí a kà yẹ sí ọlá ìlọ́po méjì, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ti ó ṣe làálàá ni ọ̀rọ̀ àti ni kíkọ́ni. 18Nítorí tí Ìwé Mímọ́ wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu,” àti pé, “Ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i.” 19Má ṣe gba ẹ̀sùn sí alàgbà kan, bí kò ṣe láti ẹnu ẹlẹ́rìí méjì mẹ́ta. 20Bá àwọn tí ó ṣẹ̀ wí níwájú gbogbo ènìyàn, kí àwọn ìyókù pẹ̀lú bà á lè bẹ̀rù. 21Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kristi Jesu, àti àwọn angẹli àyànfẹ́ kí ìwọ máa ṣàkíyèsí nǹkan wọ̀nyí, láìṣe ojúsàájú, láti fi ègbè ṣe ohunkóhun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.