Native Bible

1 Timothy 5:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí tí Ìwé Mímọ́ wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu,” àti pé, “Ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i.”

1 Timothy 5:18 in English

1 Timothy 5:18 · Berean Standard Bible

For the Scripture says, “Do not muzzle an ox while it is treading out the grain,”* and, “The worker is worthy of his wages.”*

Context

16Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tí ó gbàgbọ́ bá ní àwọn opó, kí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, kí a má sì di ẹrù lé ìjọ, kí wọn lè máa ran àwọn ti í ṣe opó nítòótọ́ lọ́wọ́. 17Àwọn alàgbà ti ó ṣe àkóso dáradára ni kí a kà yẹ sí ọlá ìlọ́po méjì, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ti ó ṣe làálàá ni ọ̀rọ̀ àti ni kíkọ́ni. 18Nítorí tí Ìwé Mímọ́ wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu,” àti pé, “Ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i.” 19Má ṣe gba ẹ̀sùn sí alàgbà kan, bí kò ṣe láti ẹnu ẹlẹ́rìí méjì mẹ́ta. 20Bá àwọn tí ó ṣẹ̀ wí níwájú gbogbo ènìyàn, kí àwọn ìyókù pẹ̀lú bà á lè bẹ̀rù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.