Native Bible

1 Timothy 5:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tí ó gbàgbọ́ bá ní àwọn opó, kí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, kí a má sì di ẹrù lé ìjọ, kí wọn lè máa ran àwọn ti í ṣe opó nítòótọ́ lọ́wọ́.

1 Timothy 5:16 in English

1 Timothy 5:16 · Berean Standard Bible

If any believing woman has dependent widows, she must assist them and not allow the church to be burdened, so that it can help the widows who are truly in need.

Context

14Nítorí náà, mo fẹ́ kí àwọn opó tí kò dàgbà máa gbéyàwó, kí wọn máa bímọ, kí wọn máa ṣe alábojútó ilé, kí wọn má ṣe fi ààyè sílẹ̀ rárá fún ọ̀tá náà láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn. 15Nítorí àwọn mìíràn ti yípadà kúrò sí ẹ̀yìn Satani. 16Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tí ó gbàgbọ́ bá ní àwọn opó, kí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, kí a má sì di ẹrù lé ìjọ, kí wọn lè máa ran àwọn ti í ṣe opó nítòótọ́ lọ́wọ́. 17Àwọn alàgbà ti ó ṣe àkóso dáradára ni kí a kà yẹ sí ọlá ìlọ́po méjì, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ti ó ṣe làálàá ni ọ̀rọ̀ àti ni kíkọ́ni. 18Nítorí tí Ìwé Mímọ́ wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu,” àti pé, “Ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.