1 Timotiu 5:21
1 Timothy 5:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kristi Jesu, àti àwọn angẹli àyànfẹ́ kí ìwọ máa ṣàkíyèsí nǹkan wọ̀nyí, láìṣe ojúsàájú, láti fi ègbè ṣe ohunkóhun.
1 Timothy 5:21 in English
1 Timothy 5:21 · Berean Standard Bible
I solemnly charge you before God and Christ Jesus and the elect angels to maintain these principles without bias, and to do nothing out of partiality.
Context
19Má ṣe gba ẹ̀sùn sí alàgbà kan, bí kò ṣe láti ẹnu ẹlẹ́rìí méjì mẹ́ta. 20Bá àwọn tí ó ṣẹ̀ wí níwájú gbogbo ènìyàn, kí àwọn ìyókù pẹ̀lú bà á lè bẹ̀rù. 21Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kristi Jesu, àti àwọn angẹli àyànfẹ́ kí ìwọ máa ṣàkíyèsí nǹkan wọ̀nyí, láìṣe ojúsàájú, láti fi ègbè ṣe ohunkóhun. 22Má ṣe fi ìkánjú gbe ọwọ́ lé ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì ṣe jẹ́ alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn, pa ara rẹ mọ́ ní ìwà mímọ́. 23Ma ṣe máa mu omi nìkan, ṣùgbọ́n máa lo wáìnì díẹ̀ nítorí inú rẹ, àti nítorí àìlera ìgbàkúgbà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.