1 Tẹsalonika 5:15
1 Thessalonians 5:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ rí i pé kò sí ẹni tí ó fi búburú san búburú, ṣùgbọ́n ẹ máa lépa èyí tí í ṣe rere láàrín ara yín àti sí ènìyàn gbogbo.
1 Thessalonians 5:15 in English
1 Thessalonians 5:15 · Berean Standard Bible
Make sure that no one repays evil for evil. Always pursue what is good for one another and for all people.
Context
13Ẹ bu ọlá fún wọn gidigidi nínú ìfẹ́, nítorí iṣẹ́ wọn. Ẹ sì máa wà ní àlàáfíà láàrín ara yín. 14Ẹ̀yin ará mi, ẹ kìlọ̀ fún àwọn ọ̀lẹ ti ó wà láàrín yín, ẹ gba àwọn tí ẹ̀rù ń bà ní ìyànjú, ẹ tọ́jú àwọn aláìlera pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí ẹ sì ní sùúrù pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. 15Ẹ rí i pé kò sí ẹni tí ó fi búburú san búburú, ṣùgbọ́n ẹ máa lépa èyí tí í ṣe rere láàrín ara yín àti sí ènìyàn gbogbo. 16Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo. 17Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.