1 Samuẹli 6:6
1 Samuel 6:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ni ó dé tí ẹ fi ń sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Ejibiti àti Farao ti ṣe? Nígbà tí ó fi ọwọ́ líle mú wọn, ṣé wọn kò rán àwọn ọmọ Israẹli jáde kí wọn kí ó lè lọ ní ọ̀nà wọn?
1 Samuel 6:6 in English
1 Samuel 6:6 · Berean Standard Bible
Why harden * your hearts as the Egyptians and Pharaoh hardened theirs? When He afflicted them, did they not send the people on their way as they departed?
Context
4Àwọn ará Filistini béèrè pé, “Irú ẹbọ ẹ̀bi wo ni kí a fi fún un?”
Wọ́n dáhùn, “Wúrà oníkókó márùn-ún àti eku ẹ̀lírí wúrà márùn-ún, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn aláṣẹ Filistini, nítorí àjàkálẹ̀-ààrùn kan náà ni ó kọlù yín àti olórí yín. 5Mọ àwòrán ààrùn oníkókó àti ti eku ẹ̀lírí yin tí ó ń ba orílẹ̀-èdè náà jẹ́ kí o sì bu ọlá fún Ọlọ́run Israẹli. Bóyá yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lára yín, lára ọlọ́run yín àti lára ilẹ̀ yín. 6Kí ni ó dé tí ẹ fi ń sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Ejibiti àti Farao ti ṣe? Nígbà tí ó fi ọwọ́ líle mú wọn, ṣé wọn kò rán àwọn ọmọ Israẹli jáde kí wọn kí ó lè lọ ní ọ̀nà wọn? 7“Nísinsin yìí ẹ pèsè kẹ̀kẹ́ ẹrù tuntun sílẹ̀, pẹ̀lú màlúù méjì tí ó ti fi ọmú fún ọmọ, èyí tí a kò tí ì gba àjàgà sí ọrùn rí, kí ẹ sì so ó mọ́ kẹ̀kẹ́ náà, kí ẹ sì mú ọmọ wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn wá sí ilé láti so. 8Kí ẹ sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa sí orí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kí ẹ̀yin sì kó àwọn ohun èlò wúrà tí ẹ̀yin fi fún un gẹ́gẹ́ bí ti ẹbọ ẹ̀bi sí inú àpótí ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó sì rán an lọ,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.