1 Samuẹli 6:4
1 Samuel 6:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ará Filistini béèrè pé, “Irú ẹbọ ẹ̀bi wo ni kí a fi fún un?” Wọ́n dáhùn, “Wúrà oníkókó márùn-ún àti eku ẹ̀lírí wúrà márùn-ún, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn aláṣẹ Filistini, nítorí àjàkálẹ̀-ààrùn kan náà ni ó kọlù yín àti olórí yín.
1 Samuel 6:4 in English
1 Samuel 6:4 · Berean Standard Bible
“What guilt offering should we send back to Him?” asked the Philistines. “Five gold tumors and five gold rats,” they said, “according to the number of rulers of the Philistines, since the same plague has struck both you and your rulers.
Context
2àwọn ará Filistini pe àwọn àlùfáà, àti àwọn alásọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì sọ pé, “Kí ni kí a ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa? Sọ fún wa bí àwa yóò ti dá a padà sí ààyè rẹ̀.” 3Wọ́n dáhùn wí pé, “Tí ẹ bá dá àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ti àwọn ọmọ Israẹli padà, ẹ má ṣe dá a padà ní òfìfo, ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ó rí, ẹ fún un ní ẹbọ ẹ̀bi. Nígbà náà ni a ó mú un yín láradá, ẹ̀yin yóò sì mọ ìdí tí ọwọ́ rẹ̀ kò fi tí ì kúrò lára yín.” 4Àwọn ará Filistini béèrè pé, “Irú ẹbọ ẹ̀bi wo ni kí a fi fún un?”
Wọ́n dáhùn, “Wúrà oníkókó márùn-ún àti eku ẹ̀lírí wúrà márùn-ún, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn aláṣẹ Filistini, nítorí àjàkálẹ̀-ààrùn kan náà ni ó kọlù yín àti olórí yín. 5Mọ àwòrán ààrùn oníkókó àti ti eku ẹ̀lírí yin tí ó ń ba orílẹ̀-èdè náà jẹ́ kí o sì bu ọlá fún Ọlọ́run Israẹli. Bóyá yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lára yín, lára ọlọ́run yín àti lára ilẹ̀ yín. 6Kí ni ó dé tí ẹ fi ń sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Ejibiti àti Farao ti ṣe? Nígbà tí ó fi ọwọ́ líle mú wọn, ṣé wọn kò rán àwọn ọmọ Israẹli jáde kí wọn kí ó lè lọ ní ọ̀nà wọn?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.