Native Bible

1 Samuel 6:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mọ àwòrán ààrùn oníkókó àti ti eku ẹ̀lírí yin tí ó ń ba orílẹ̀-èdè náà jẹ́ kí o sì bu ọlá fún Ọlọ́run Israẹli. Bóyá yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lára yín, lára ọlọ́run yín àti lára ilẹ̀ yín.

1 Samuel 6:5 in English

1 Samuel 6:5 · Berean Standard Bible

Make images of your tumors and of the rats that are ravaging the land. Give glory to the God of Israel, and perhaps He will lift His hand from you and your gods and your land.

Context

3Wọ́n dáhùn wí pé, “Tí ẹ bá dá àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ti àwọn ọmọ Israẹli padà, ẹ má ṣe dá a padà ní òfìfo, ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ó rí, ẹ fún un ní ẹbọ ẹ̀bi. Nígbà náà ni a ó mú un yín láradá, ẹ̀yin yóò sì mọ ìdí tí ọwọ́ rẹ̀ kò fi tí ì kúrò lára yín.” 4Àwọn ará Filistini béèrè pé, “Irú ẹbọ ẹ̀bi wo ni kí a fi fún un?” Wọ́n dáhùn, “Wúrà oníkókó márùn-ún àti eku ẹ̀lírí wúrà márùn-ún, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn aláṣẹ Filistini, nítorí àjàkálẹ̀-ààrùn kan náà ni ó kọlù yín àti olórí yín. 5Mọ àwòrán ààrùn oníkókó àti ti eku ẹ̀lírí yin tí ó ń ba orílẹ̀-èdè náà jẹ́ kí o sì bu ọlá fún Ọlọ́run Israẹli. Bóyá yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lára yín, lára ọlọ́run yín àti lára ilẹ̀ yín. 6Kí ni ó dé tí ẹ fi ń sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Ejibiti àti Farao ti ṣe? Nígbà tí ó fi ọwọ́ líle mú wọn, ṣé wọn kò rán àwọn ọmọ Israẹli jáde kí wọn kí ó lè lọ ní ọ̀nà wọn? 7“Nísinsin yìí ẹ pèsè kẹ̀kẹ́ ẹrù tuntun sílẹ̀, pẹ̀lú màlúù méjì tí ó ti fi ọmú fún ọmọ, èyí tí a kò tí ì gba àjàgà sí ọrùn rí, kí ẹ sì so ó mọ́ kẹ̀kẹ́ náà, kí ẹ sì mú ọmọ wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn wá sí ilé láti so.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.