1 Samuẹli 6:8
1 Samuel 6:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ẹ sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa sí orí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kí ẹ̀yin sì kó àwọn ohun èlò wúrà tí ẹ̀yin fi fún un gẹ́gẹ́ bí ti ẹbọ ẹ̀bi sí inú àpótí ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó sì rán an lọ,
1 Samuel 6:8 in English
1 Samuel 6:8 · Berean Standard Bible
Take the ark of the LORD, set it on the cart, and in a chest beside it put the gold objects you are sending Him as a guilt offering. Then send the ark on its way,
Context
6Kí ni ó dé tí ẹ fi ń sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Ejibiti àti Farao ti ṣe? Nígbà tí ó fi ọwọ́ líle mú wọn, ṣé wọn kò rán àwọn ọmọ Israẹli jáde kí wọn kí ó lè lọ ní ọ̀nà wọn? 7“Nísinsin yìí ẹ pèsè kẹ̀kẹ́ ẹrù tuntun sílẹ̀, pẹ̀lú màlúù méjì tí ó ti fi ọmú fún ọmọ, èyí tí a kò tí ì gba àjàgà sí ọrùn rí, kí ẹ sì so ó mọ́ kẹ̀kẹ́ náà, kí ẹ sì mú ọmọ wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn wá sí ilé láti so. 8Kí ẹ sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa sí orí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kí ẹ̀yin sì kó àwọn ohun èlò wúrà tí ẹ̀yin fi fún un gẹ́gẹ́ bí ti ẹbọ ẹ̀bi sí inú àpótí ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó sì rán an lọ, 9ṣùgbọ́n kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ. Tí ó bá ń lọ sí ilẹ̀ rẹ̀, ìlú rẹ̀, níhà Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà ni Olúwa mú àjálù ńlá yìí bá wa. Ṣùgbọ́n bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà náà ni a mọ̀ pé kì í ṣe ọwọ́ rẹ̀ ni ó kọlù wá, ṣùgbọ́n ó wá bẹ́ẹ̀ ni.” 10Nígbà náà ni wọ́n ṣe èyí. Wọ́n mú abo màlúù méjì, tí ń fi ọmú fún ọmọ, wọn mọ́ ara, wọ́n sì dè é ni ilé kẹ̀kẹ́ ẹrù, wọn sì so àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀ ni ilé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.