1 Samuẹli 30:20
1 Samuel 30:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi sì kó gbogbo àgùntàn, àti màlúù tí àwọn ènìyàn rẹ̀ dà ṣáájú àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn tí wọ́n gbà, wọ́n sì wí pé, “Èyí yìí ni ìkógun ti Dafidi.”
1 Samuel 30:20 in English
1 Samuel 30:20 · Berean Standard Bible
And he recovered all the flocks and herds, which his men drove ahead of the other livestock, calling out, “This is David’s plunder!”
Context
18Dafidi sì gbà gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki ti kó: Dafidi sì gba àwọn obìnrin rẹ̀ méjèèjì. 19Kò sì ṣí nǹkan tí ó kù fún wọn, kékeré tàbí ńlá, ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin, tàbí ìkógun, tàbí gbogbo nǹkan tí wọ́n ti kó: Dafidi sì gba gbogbo wọn. 20Dafidi sì kó gbogbo àgùntàn, àti màlúù tí àwọn ènìyàn rẹ̀ dà ṣáájú àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn tí wọ́n gbà, wọ́n sì wí pé, “Èyí yìí ni ìkógun ti Dafidi.” 21Dafidi sì wá sọ́dọ̀ igba ọkùnrin tí àárẹ̀ ti mú jú, tiwọn kò lè tọ́ Dafidi lẹ́yìn mọ́, ti òun ti fi sílẹ̀, ni àfonífojì Besori: wọ́n sì lọ pàdé Dafidi, àti láti pàdé àwọn ènìyàn tí ó lọ pẹ̀lú rẹ̀: Dafidi sì pàdé àwọn ènìyàn náà, ó sì kí wọn. 22Gbogbo àwọn ènìyàn búburú àti àwọn ọmọ Beliali nínú àwọn tí o bá Dafidi lọ sì dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Bí wọn kò ti bá wa lọ, àwa ki yóò fi nǹkan kan fún wọn nínú ìkógun ti àwa rí gbà bí kò ṣe obìnrin olúkúlùkù wọn, àti ọmọ wọn; ki wọn sì mú wọn, ki wọn sì máa lọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.