Native Bible

1 Samuel 30:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo àwọn ènìyàn búburú àti àwọn ọmọ Beliali nínú àwọn tí o bá Dafidi lọ sì dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Bí wọn kò ti bá wa lọ, àwa ki yóò fi nǹkan kan fún wọn nínú ìkógun ti àwa rí gbà bí kò ṣe obìnrin olúkúlùkù wọn, àti ọmọ wọn; ki wọn sì mú wọn, ki wọn sì máa lọ.”

1 Samuel 30:22 in English

1 Samuel 30:22 · Berean Standard Bible

but all the wicked and worthless men among those who had gone with David said, “Because they did not go with us, we will not share with them the plunder we recovered, except for each man’s wife and children. They may take them and go.”

Context

20Dafidi sì kó gbogbo àgùntàn, àti màlúù tí àwọn ènìyàn rẹ̀ dà ṣáájú àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn tí wọ́n gbà, wọ́n sì wí pé, “Èyí yìí ni ìkógun ti Dafidi.” 21Dafidi sì wá sọ́dọ̀ igba ọkùnrin tí àárẹ̀ ti mú jú, tiwọn kò lè tọ́ Dafidi lẹ́yìn mọ́, ti òun ti fi sílẹ̀, ni àfonífojì Besori: wọ́n sì lọ pàdé Dafidi, àti láti pàdé àwọn ènìyàn tí ó lọ pẹ̀lú rẹ̀: Dafidi sì pàdé àwọn ènìyàn náà, ó sì kí wọn. 22Gbogbo àwọn ènìyàn búburú àti àwọn ọmọ Beliali nínú àwọn tí o bá Dafidi lọ sì dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Bí wọn kò ti bá wa lọ, àwa ki yóò fi nǹkan kan fún wọn nínú ìkógun ti àwa rí gbà bí kò ṣe obìnrin olúkúlùkù wọn, àti ọmọ wọn; ki wọn sì mú wọn, ki wọn sì máa lọ.” 23Dafidi sì wí pé, “Ẹ má ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ara mi: Olúwa ni ó fi nǹkan yìí fún wa, òun ni ó sì pa wá mọ́, òun ni ó sì fi ẹgbẹ́ ogun ti ó dìde sí wa lé wa lọ́wọ́. 24Ta ni yóò gbọ́ tiyín nínú ọ̀ràn yìí? Ṣùgbọ́n bi ìpín ẹni tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ si ìjà ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ìpín ẹni ti ó dúró ti ẹrù; wọn ó sì pín in bákan náà.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.