1 Samuẹli 30:18
1 Samuel 30:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi sì gbà gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki ti kó: Dafidi sì gba àwọn obìnrin rẹ̀ méjèèjì.
1 Samuel 30:18 in English
1 Samuel 30:18 · Berean Standard Bible
So David recovered everything the Amalekites had taken, including his two wives.
Context
16Ó sì mú un sọ̀kalẹ̀, sì wò ó, wọ́n sì tàn ká ilẹ̀, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń jó, nítorí ìkógun púpọ̀ tí wọ́n kó láti ilẹ̀ àwọn Filistini wá, àti láti ilẹ̀ Juda. 17Dafidi sì pa wọ́n láti àfẹ̀mọ́júmọ́ títí ó fi di àṣálẹ́ ọjọ́ kejì: kò sí ẹnìkan tí ó là nínú wọn, bí kọ̀ ṣe irinwó (400) ọmọkùnrin tí wọ́n gun ìbákasẹ tí wọ́n sì sá. 18Dafidi sì gbà gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki ti kó: Dafidi sì gba àwọn obìnrin rẹ̀ méjèèjì. 19Kò sì ṣí nǹkan tí ó kù fún wọn, kékeré tàbí ńlá, ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin, tàbí ìkógun, tàbí gbogbo nǹkan tí wọ́n ti kó: Dafidi sì gba gbogbo wọn. 20Dafidi sì kó gbogbo àgùntàn, àti màlúù tí àwọn ènìyàn rẹ̀ dà ṣáájú àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn tí wọ́n gbà, wọ́n sì wí pé, “Èyí yìí ni ìkógun ti Dafidi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.