Native Bible

1 Samuel 29:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣé èyí ni Dafidi tiwọn torí rẹ̀ gberin ara wọn nínú ijó wí pé, “ ‘Saulu pa ẹgbẹ̀rún rẹ̀, Dafidi si pa ẹgbẹgbàarùn-ún tirẹ̀.’ ”

1 Samuel 29:5 in English

1 Samuel 29:5 · Berean Standard Bible

Is this not the David about whom they sing in their dances: ‘Saul has slain his thousands, and David his tens of thousands’?”

Context

3Àwọn ìjòyè Filistini sì béèrè wí pé, “Kín ni àwọn Heberu ń ṣe níhìn-ín yìí?” Akiṣi sì wí fún àwọn ìjòyè Filistini pé “Dafidi kọ yìí, ìránṣẹ́ Saulu ọba Israẹli, tí ó wà lọ́dọ̀ mi láti ọjọ́ wọ̀nyí tàbí láti ọdún wọ̀nyí, èmi kò ì tì í rí àṣìṣe kan ni ọwọ́ rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí.” 4Àwọn ìjòyè Filistini sì bínú sí i; àwọn ìjòyè Filistini sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí ọkùnrin yìí padà kí ó sì lọ sí ipò rẹ̀ tí ó fi fún un, kí ó má sì jẹ́ kí ó bá wa sọ̀kalẹ̀ lọ sí ogun, kí ó má ba à jásí ọ̀tá fún wa ni ogun, kín ni òun ó fi ba olúwa rẹ̀ làjà, orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kọ́? 5Ṣé èyí ni Dafidi tiwọn torí rẹ̀ gberin ara wọn nínú ijó wí pé, “ ‘Saulu pa ẹgbẹ̀rún rẹ̀, Dafidi si pa ẹgbẹgbàarùn-ún tirẹ̀.’ ” 6Akiṣi sì pe Dafidi, ó sì wí fún un pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ìwọ jẹ́ olóòótọ́ àti ẹni ìwà rere lójú mi, ní àlọ rẹ àti ààbọ̀ rẹ pẹ̀lú mi ní ogun: nítorí pé èmi ko tí ì ri búburú kan lọ́wọ́ rẹ́ láti ọjọ́ ti ìwọ ti tọ̀ mí wá, títí o fi dì òní yìí ṣùgbọ́n lójú àwọn ìjòyè, ìwọ kò ṣe ẹni tí ó tọ́. 7Ǹjẹ́ yípadà kí o sì máa lọ ní àlàáfíà, kí ìwọ má ṣe bà àwọn Filistini nínú jẹ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.