1 Samuẹli 29:4
1 Samuel 29:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ìjòyè Filistini sì bínú sí i; àwọn ìjòyè Filistini sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí ọkùnrin yìí padà kí ó sì lọ sí ipò rẹ̀ tí ó fi fún un, kí ó má sì jẹ́ kí ó bá wa sọ̀kalẹ̀ lọ sí ogun, kí ó má ba à jásí ọ̀tá fún wa ni ogun, kín ni òun ó fi ba olúwa rẹ̀ làjà, orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kọ́?
1 Samuel 29:4 in English
1 Samuel 29:4 · Berean Standard Bible
But the commanders of the Philistines were angry with Achish and told him, “Send that man back and let him return to the place you assigned him. He must not go down with us into battle only to become our adversary during the war. What better way for him to regain the favor of his master than with the heads of our men?
Context
2Àwọn ìjòyè Filistini sì kọjá ní ọ̀rọ̀ọ̀rún àti lẹgbẹẹgbẹ̀rún; Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú Akiṣi sì kẹ́yìn. 3Àwọn ìjòyè Filistini sì béèrè wí pé, “Kín ni àwọn Heberu ń ṣe níhìn-ín yìí?”
Akiṣi sì wí fún àwọn ìjòyè Filistini pé “Dafidi kọ yìí, ìránṣẹ́ Saulu ọba Israẹli, tí ó wà lọ́dọ̀ mi láti ọjọ́ wọ̀nyí tàbí láti ọdún wọ̀nyí, èmi kò ì tì í rí àṣìṣe kan ni ọwọ́ rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí.” 4Àwọn ìjòyè Filistini sì bínú sí i; àwọn ìjòyè Filistini sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí ọkùnrin yìí padà kí ó sì lọ sí ipò rẹ̀ tí ó fi fún un, kí ó má sì jẹ́ kí ó bá wa sọ̀kalẹ̀ lọ sí ogun, kí ó má ba à jásí ọ̀tá fún wa ni ogun, kín ni òun ó fi ba olúwa rẹ̀ làjà, orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kọ́? 5Ṣé èyí ni Dafidi tiwọn torí rẹ̀ gberin ara wọn nínú ijó wí pé,
“ ‘Saulu pa ẹgbẹ̀rún rẹ̀,
Dafidi si pa ẹgbẹgbàarùn-ún tirẹ̀.’ ” 6Akiṣi sì pe Dafidi, ó sì wí fún un pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ìwọ jẹ́ olóòótọ́ àti ẹni ìwà rere lójú mi, ní àlọ rẹ àti ààbọ̀ rẹ pẹ̀lú mi ní ogun: nítorí pé èmi ko tí ì ri búburú kan lọ́wọ́ rẹ́ láti ọjọ́ ti ìwọ ti tọ̀ mí wá, títí o fi dì òní yìí ṣùgbọ́n lójú àwọn ìjòyè, ìwọ kò ṣe ẹni tí ó tọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.