Native Bible

1 Samuel 24:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, àyà já Dafidi nítorí tí ó gé etí aṣọ Saulu.

1 Samuel 24:5 in English

1 Samuel 24:5 · Berean Standard Bible

Afterward, David’s conscience was stricken because he had cut off the corner of Saul’s robe.

Context

3Ó sì dé ibi àwọn agbo àgùntàn tí ó wà ní ọ̀nà, ihò kan sì wà níbẹ̀, Saulu sì wọ inú rẹ̀ lọ láti bo ẹsẹ̀ rẹ̀, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń bẹ lẹ́bàá ihò náà. 4Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì wí fún un pé, “Wò ó, èyí ni ọjọ́ náà tí Olúwa wí fún ọ pé, ‘Wò ó, èmi fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, ìwọ ó sì ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ lójú rẹ.’ ” Dafidi sì dìde, ó sì yọ́ lọ gé etí aṣọ Saulu. 5Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, àyà já Dafidi nítorí tí ó gé etí aṣọ Saulu. 6Òun sì wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Èèwọ̀ ni fún mi láti ọ̀dọ́ Olúwa wá bí èmi bá ṣe nǹkan yìí sí ẹni tí a ti fi àmì òróró Olúwa yàn, láti nawọ́ mi sí i, nítorí pé ẹni àmì òróró Olúwa ni.” 7Dafidi sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọn dìde sí Saulu, Saulu sì dìde kúrò ní ihò náà, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.