1 Samuẹli 24:7
1 Samuel 24:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọn dìde sí Saulu, Saulu sì dìde kúrò ní ihò náà, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.
1 Samuel 24:7 in English
1 Samuel 24:7 · Berean Standard Bible
With these words David restrained his men, and he did not let them rise up against Saul. Then Saul left the cave and went on his way.
Context
5Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, àyà já Dafidi nítorí tí ó gé etí aṣọ Saulu. 6Òun sì wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Èèwọ̀ ni fún mi láti ọ̀dọ́ Olúwa wá bí èmi bá ṣe nǹkan yìí sí ẹni tí a ti fi àmì òróró Olúwa yàn, láti nawọ́ mi sí i, nítorí pé ẹni àmì òróró Olúwa ni.” 7Dafidi sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọn dìde sí Saulu, Saulu sì dìde kúrò ní ihò náà, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. 8Dafidi sì dìde lẹ́yìn náà, ó sì jáde kúrò nínú ihò náà ó sì kọ sí Saulu pé, “Olúwa mi, ọba!” Saulu sì wo ẹ̀yìn rẹ̀. Dafidi sì dojú rẹ́ bo ilẹ̀ ó sì tẹríba fún un. 9Dafidi sì wí fún Saulu pé, “Èéha ti ṣe tí ìwọ fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn pé, ‘Wò ó, Dafidi ń wa ẹ̀mí rẹ́’?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.